Ẹgbẹ ajijangbara fun ilẹ Yoruba jakejado, iyẹn Oodua Peoples Congress, OPC ti pariwo sita wi pe awọn ko si lara awọn ẹgbẹ ọmọ Yoruba mẹtadinlọgọta ti wọn bu ọwọ lu Oloye Bọla Ahmed Tinubu gẹgẹ bi aarẹ orileede Naijiria lọdun 2023.
Akọwe ipolongo ẹgbẹ naa, Amofin Yinka Oguntimẹhin lo sọ eyi di mimọ ninu atẹjade to gbe sita lonii, to si ni kẹnikẹni ma ṣe lo orukọ Gani Adams lati fi ṣe ọrọ oṣelu.
Oguntimẹhin sọ pe lilo orukọ OPC ati Gani Adams fun ti ipo oṣelu jẹ ọna jibiti ati gbajuẹ to jinna si otitọ.
O wa rọ awọn to n lo orukọ OPC lati fi lu jibiti wi pe ki wọn lọ jawọ, nitori pe awọn ko si lara awọn ẹgbẹ mẹtadinlọgọta to ṣe ipade l'Ekoo lati polongo idibo fun Bọla Tinubu, Yẹmi Ọṣinbajo tabi Kayọde Fayẹmi fun ipo Aarẹ.
AWIKONKO gbọ pe orukọ OPC wa lara awọn orukọ ti wọn gbe jade wi pe wọn pẹlu bawọn ṣe ipade pọ lati sọ asọyepọ nipa atunto bi ipo Aarẹ yoo ṣe ja mọ Yoruba lọwọ lọdun 2023.
No comments:
Post a Comment