Alẹ ana, Ọjọru, Wẹsidee ni asọtẹlẹ gbajugbaja Wọlii Elijah Ayọdele lori ọrọ Nnamdi Kanu tun wa si imuṣẹ wi pe yoo le koko fun un lati bọ ninu wahala to wa lati bi oṣu meloo kan sẹyin.
Ọjọ kẹtalelogun, oṣu kejila, ọdun to kọja ni Wolii Ayọdele, olori ijọ INRI to wa nilu Eko sọ awọn ohun ti yoo ṣẹlẹ lọdun yii, ati awọn ọdun to n bọ.
Wolii Ayọdele sọ pe ijọba orileede Naijiria ko tii ṣetan lati tu Kanu silẹ, nitori awọn idi pataki kan.
Ninu asọtẹlẹ naa, Wolii Ayọdele sọ pe:
"Nnamdi Kanu ko nii ri ọna irọrun. Ko maa reti awọn asiko to le koko nitori pe ijọba Naijiria ko ṣetan lati tu silẹ fun iṣẹju aaya kan. O nilo lati tẹra mọ adura, ko si wa mni ikiyesara lakooko yii. Ijọba ko nii lero lati ṣeku pa Igboho tabi Kanu."
Ni ijẹri si asọtẹlẹ naa, Aarẹ Muhammadu Buhari sọ ninu ifọrọwerọ to ṣe lanaa wi pe ko si nnkan to kan oun ninu wi pe ki wọn tu Kanu silẹ, ati pe ko lọ dahun awọn ibeere niwaju ile-ẹjọ, nitori pe ile-ẹjọ nikan lo le ri iyanju si ọrọ rẹ.
No comments:
Post a Comment