Gomina tẹlẹri nipinlẹ Ọyọ, Christopher Alao Akala ti jade laye lẹni ọdun mọkanlelaadọrin (71), lonii Ọjọru, Wẹsidee.
Akala, ọmọ bibi ilu Ogbomọṣọ naa la gbọ pe o jade laye, ninu ile ẹ to wa nilu Ogbomọṣọ.
Lara awọn to fi iroyin naa to wa leti sọ pe ṣe ni wọn ba oku Akala lori bẹẹdi, lẹyin ọpọlọpọ ọdun ti aisan kan ti n ba a finra.
Gomina Ṣeyi Makinde ti fi lẹta ibanikẹdun ranṣẹ si awọn mọlẹbi ati gbogbo ọmọ ipinlẹ Ọyọ jakejado.
No comments:
Post a Comment