Gomina ipinlẹ Kwara, AbdulRahman AbdulRazaq ti ba ẹgbẹ awọn ẹlẹsin Kristẹẹni, Christian Association of Nigeria (CAN), ẹka tipinlẹ naa kẹdun iku alaga wọn, Paul Ọlawoore.
Ọjọ Satide, Abamẹta to kọja yii ni Ọlawoore ku lẹni ọgọta ọdun.
Ninu ọrọ ibanikẹdun ti akọwe iroyin gomina, Rafiu Ajakaye fi sita, o ni ẹdun ọkan lo jẹ foun lati gbọ nipa iku agba ẹsin naa, nitori pe ẹni to ni iwa irẹlẹ pupọ ni.
O ni adanu nla ni iku ọkunrin naa jẹ nitori pe pupọ igba toun fu mọ ọn lo fi n ṣe igbelarugẹ ifẹ, iṣọkan ati alaafia loore-koore.
No comments:
Post a Comment