Gomina AbdulRahman AbdulRazaq tipinlẹ Kwara ti rawọ ẹbẹ si ileeṣẹ ologun orileede yii lati fọwọsowọpọ pẹlu ijọba ati awọn ileeṣẹ eleto aabo yooku lati ma ṣe jẹ ki ina eto aabo ipinlẹ naa jo rẹyin.
Nibi ayẹyẹ iranti awọn akọni ologun ti wọn ku soju ogun, eyi to waye laipẹ yii ni Gomina AbdulRazaq ti pe ipe yii, ti wọn si lawọn ileeṣẹ ologun ni iṣẹ to pọ lati ṣe nipa didaabobo ẹmi ati dukia awọn araalu.
AbdulRazaq ni ipa ti awọn ologun n ko ninu iṣọkan ati idagbasoke orileede Naijiria ko kere rara, nitori pe awọn ni wọn ko jẹ ki ogun ti ko Naijiria lẹru lọ.
Bẹẹ lo sọ pe o ṣe pataki lati maa ṣe iranti awọn to bogun lọ, paapaa titọju awọn to wa laye naa ko ṣee fọwọ rọ ti sẹyin.
No comments:
Post a Comment