Rúkèrúdò nlá n bọ̀ káàkiri àgbáyé àti Nàìjíríà láìpẹ́ - Wòlíì Ayọ̀délé sọ̀rọ̀ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, December 22, 2021

Rúkèrúdò nlá n bọ̀ káàkiri àgbáyé àti Nàìjíríà láìpẹ́ - Wòlíì Ayọ̀délé sọ̀rọ̀


Gbajugbaja Wolii Ọlọrun nni, Wolii Babatunde Elijah Ayọdele to jẹ alaṣẹ ati olori ijọ INRI Evangelical Spiritual Church, to wa nipinlẹ Eko ti sọ pe ki awọn eeyan kaakiri agbaye, paapaa lorileede Naijiria lọ maa gbaradi fun rukerudo ti yoo mi gbogbo agbaye titi lọdun 2022 ti a fẹẹ bọ sinu ẹ yii.
 
Wolii Ayọdele lo sọ eyi nibi ipade awọn akọroyin to maa n ṣe ni gbogbo oṣu kejila ọdun, eyi to fi maa n sọ awọn asọtẹlẹ ohun ti yoo ṣẹlẹ lọdun tuntun sita.
 
Kolonka awọn asọtẹlẹ Wolii Ayọdele lo ti wa si imuṣẹ, ti awọn eeyan si ti jẹrii sii wi pe lotitọ ni Ọlọrun fi iṣẹ ran an, kii ṣe alatẹnujẹ Wolii.
 
Nigba to n sọrọ ninu ṣọọṣi rẹ, o sọ pe afi ki awọn eeyan lọ maa gbadura gidigidi, lọsan ati loru lati ma baa kagbako awọn nnkan buburu to wa ninu ọdun 2022.
 
Bo ṣe sọrọ lori ọrọ oṣelu, lo sọ nipa ti eto ọrọ aje, ere idaraya, ajọ agbaye, orileede lagbaye, Naijiria, ajakalẹ arun, ati bẹẹbẹẹlọ.
 
Ninu ọrọ rẹ, olori ijọ INRI naa sọ pe
“Ẹmi Ọlọrun sọ fun mi wi pe oriṣiriṣi ohun nla ni yoo ṣẹlẹ lọdun 2022, eyi ti yoo mi agbaye ati awọn adari agbaye titi. Mo ri awọn nnkan bii pe eto ọrọ aje n mi jolonjolo, aisi eto aabo, ailera, iyipada oju ọjọ.
 
“Mo rii wi pe ọgọfa ọjọ lorileede Naijiria ati nilẹ Afrika ko nii rọrun rara nitori ajakalẹ arun korona, eyi ti yoo gba ọna miran yọ sita. Ẹmi Ọlọrun sọ fun mi pe iji nla lile kan yoo ja, eyi ti yoo mu ijamba kaakiri agbaye, ati lorileede Naijriia. Mo rii wi pe ajakalẹ arun tuntun miran tun dide lagbaye lọdun 2022.
 
“Ẹ je ka gbadura ka ma ṣe padanu aarẹ tẹlẹri lorileede yii, ati aarẹ to wa nipo, yala boya wọn yoo ṣubu lulẹ tabi pe ki wọn ni ipenija ilera.
 
“Ẹ jẹ ka gbadura lodi igbajọba awọn ologun lawọn ilẹ Afrika ati orileede agbaye kan. Mo rii pe wi pe alaafia ko nii jọba lagbaye nitori awọn ohun kan yoo dide. Mo rii wi pe gbajugbaja agbabọọlu agbaye kan, olorin ati afẹṣẹkubiojo agbaye yoo ku. Mo ri iku agbaye onkọwe agbaye kan. Ẹmi Ọlọrun sọ pe a ni lati gbadura gidi ki awọn ohun buruku to fẹẹ ṣẹlẹ lọdun 2022 le dawọ duro.
 
“Ajakalẹ arun korona, ẹlẹẹkẹrin iru ẹ to n bọ yoo mi ilẹ Amẹrika mejeeji {United States fo America ati United Kindom} titi, ti yoo si ṣe ipalara fun wọn, koda, awọn orileede kan yoo tilẹkun wọn pa lapa kan.”
 
Siwaju sii nigba to n sọrọ lori ọrọ oṣelu Naijiria, Wolii Ayọdele sọ pe 
“Awọn kabaa kan ninu ẹgbẹ oṣelu PDP yoo dide lodi si alaga wọn. PDP gbọdọ wa ni ikiyesara lati ma ṣe aṣiṣẹ ti yoo tun jẹ ki wọn padanu anfaani lati pada si iṣakoso.
 
“Mo rii wi pe ipinya agbara yoo wa ni Naijiria lọjọ iwaju. Awọn olori ile igbimọ aṣofin nipinlẹ kan yoo paṣẹ ti ara wọn, ọpọ awọn nnkan ni wọn ko nii gbe gba iwaju awọn gomina mọ. Ijọba Buhari yoo kuna lati sọrọ lori awọn iṣoro to n koju eto ọrọ aabo, ajẹbanu, Fulani darandaran ati awọn miran.
 
“Ijọba yoo sare tẹle awọn ijọ kan lorileede Naijiria. Awọn eeyan yoo fẹhonu han lori bawọn ọlọpaa ṣe n ṣeeṣi pawọn eeyan.”

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI