Olú tìlu Wasinmi l'Ógùn wàjà lójijì - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, December 13, 2021

Olú tìlu Wasinmi l'Ógùn wàjà lójijì


Iroyin to tẹ wa lọwọ ti jẹ ko di mimọ pe Olu tilu Wasinmi, nipinlẹ Ogun, Ọba Babatunde Ọṣuntoogun, Gbadewọlu kinni ti waja.

Ana, ọjọ Aiku, Sannde la gbọ pe Kabiyesi naa waja ni ọsibitu FMC to wa ni Idi-Aba nilu Abẹokuta, ipinlẹ naa.

AWIKONKO gbọ pe ṣe ni Ọba Ọṣuntoogun yọ ṣubu ninu aafin rẹ, ko to di pe wọn gbe e digbadigba lọ si ọsibitu lati doola ẹmi rẹ.


No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI