Ọlọ́run kò tíì bá mi sọ̀rọ̀ bóyá Tinubu máa du ipò Ààrẹ lọ́dún 2023 - Gbajúmọ̀ Bíṣọ̀ọ̀bù pariwo síta - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, December 21, 2021

Ọlọ́run kò tíì bá mi sọ̀rọ̀ bóyá Tinubu máa du ipò Ààrẹ lọ́dún 2023 - Gbajúmọ̀ Bíṣọ̀ọ̀bù pariwo síta


Alaṣẹ ati oludasilẹ ṣọọṣi Bible Life Church Cathedral nilu Eko, Biṣọọbu Leonard Umunna ti sọ pe bo tilẹ jẹ pe Ọlọrun ko tii ba oun sọrọ lori bọya Aṣiwaju ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC, Bọla Ahmẹd Tinubu yoo jade du ipo Aarẹ orilẹ-ede Naijiria lọdun 2023, sibẹ, o jẹ ko di mimọ pe oun ti ṣetan lati ṣagbatẹru rẹ ni gbogbo ọna.
 
Biṣọọbu Leonard Umunna sọ pe Tinubu dara ju awọn agba Yoruba kan lọ, nitori pe iṣakoso rẹ lakooko to wa nipo gomina ipinlẹ Eko tu gbogbo araalu lara, to si tun fa eeyan gidi kalẹ, iyẹn Babaunde Faṣọla nigba to kuro nijọba.
 
O tẹsiwaju ninu ọrọ rẹ pe Bọla Ahmẹd Tinubu nikan lo yẹ, to si dara fun ipo Aarẹ lọdun 2023.
 
Ninu ifọrọwerọ ti Biṣọọbu naa ṣe pẹlu akọroyin iwe iroyin The Guardian, lo ti sọrọ yii jade, to si ni Ọlọrun ko tii fi erongba Tinubu lati jade du ipo Aarẹ han oun, ṣugbọn to sọ pe ẹnikan ṣoṣo to tun le ṣakoso ijọba Naijiria daadaa niyẹn.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI