Iroyin to tẹ wa lọwọ bayii ti fidi rẹ mulẹ wi pe awọn agbebọn kan ti pa Magajin Garin Idasu nijọba ibilẹ Giwa, ipinlẹ Kaduna, Malamu Magaji Ibrahim danu.
Awọn agbebọn naa pa Malamu Ibrahim lẹyin wakati mẹrinlelogun ti wọn ṣeku pa awọn mejidinlogoji kaakiri ipinlẹ Kaduna.
Ọkan lara awọn olori ọdọ labule Rahiya, Ridwan Abdulhadi, to bawọn akọroyin sọrọ sọ pe ida aadọrin lawọn araalu ti wọn ti sa kuro, lati lọ farapamọ sawọn ilu bii Zaria ati Giwa.
Ọjọ Aiku, Sannde la gbọ pe wọn ṣeku pa Malaamu Ibrahim lakooko ikọlu awọn agbebọn ọhun.
No comments:
Post a Comment