Onidajọ Mahmud Abdulgafar, ti ile-ẹjọ giga ipinlẹ Kwara ti ju gendekunrin ọmọ ọdun mọkandinlọgbọn kan, Joshua Ajayi Oluwatobi sẹwọn ọdun mejidinlọgbọn pẹlu iṣẹ aṣekara.
A gbọ pe ṣe ni Joshua n fi orukọ ọkan lara awọn ọga agba to n ri sọrọ awọn akẹkọọ ni fasiti ilu Ilọrin lu awọn eeyan ni jibiti owo ileewe ati owo ilegbe awọn akẹkọọ ti a mọ si hostel.
Esun mẹrin ọtọọtọ la gbọ pe ajọ to n gbogun ti iwa jibiti ati ajẹbanu lorilẹ-ede yii, Economic and Financial Crimes Commission (EFCC) fi kan Joshua niwaju il-ẹjọ.
Wọn ni gbogbo awọn akẹkọọ ti wọn ba n wa ile ti wọn yoo gbe, atawọn to ba fẹẹ san owo ileewe wọn ni Joshua maa n tan jẹ, ti yoo si gba owo naa lọwọ wọn.
Onidajọ Abdulgafar nigba to n gbe idajọ rẹ kalẹ, o sọ pe awọn ẹri to wa niwaju oun nipa Joshua kọja ohun wọn le maa fọwọ bo, ati pe oun funra rẹ ti jẹwọ pe lotitọ ni, fun idi eyi, o ni idajọ to tọ sii ni lati lọ fi ẹwọn ọdun mejidinlọgbọn gbara.
AWIKONKO gbọ pe ninu oṣu kẹfa, ọdun 2020, ni Onidajọ Sikiru Oyinloye ti ile-ẹjọ giga ipinlẹ Kwara ju Joshua sẹwọn lori ẹsun jibiti, to si lo igba diẹ ni ọgba ẹwọn Mandala, ko to di pe o pada gba ominira.
Wọn ni ko si bi a o ti ṣe ebolo ti ko nii run igbẹ, idi ree ti wọn ni Joshua tun fi pada sidi iwa jibiti to yan laayo, nitori igbagbọ to ni si ara rẹ wi pe nipa iwa jibiti nikan loun le fi di ọlọla laye.
No comments:
Post a Comment