Alaṣẹ ati oludasilẹ ṣọọṣi Omega Fire International Ministry, Wolii Johnson Suleman ti pariwo sita fun gbogbo awọn ọkunrin lati yago fun fifun awọn obinrin lowo, paapaa lakoko pọpọṣinṣin ọdun to wa nita yii, iyẹn Keresimesi.
Wolii Suleman lakooko to n sọrọ ninu ṣọọṣi rẹ lọjọ isinmi, Aiku, Sannde to kọja yii sọ pe kii ṣe awọn iyawo ile o, bi ko ṣe pe awọn ọrẹbinrin ikọkọ.
O ṣalaye nibẹ bi oriṣiriṣi ibadọrẹ ṣe n fori ṣanpọn lakooko ti a wa yii, ti awọn obinrin si ti sọ ibadọrẹ di okoowo ti wọn yoo ti maa ri owo, ati pe ipinnu wọn ni lati maa gba owo lọwọ awọn ọkunrin lati le fi gbọ bukata ara wọn.
Bakan naa lo gba awọn ọkunrin ti wọn ko tii ṣe igbeyawo lamọran lati ma ṣe fun awọn ọrẹbinrin wọn lọwọ, ki wọn wa pa mama to bi bi wọn ti sẹgbẹ kan.
“Gendekunrin kan pade ọdọmọkunrin kan, ohun akọkọ to si kọkọ beere ni pe kini yoo fun oun? Ṣe ọrọ okoowo ni ibadọrẹ wa jẹ bayii ni? Bi obinrin kan ba beere pe ki lo maa fun oun, iwọ naa beere lọwọ ẹ wi pe ki lo maa fun ẹ tabi pe ki lo ti fun ẹ. O ko nilo lati pa mama rẹ ti, ki o wa lọ fun obinrin to ṣi wa loju ọna lowo, eyi ti ko tii si igbagbọ wi pe ẹ maa fẹ ara yin.
"Mo n gba ẹ lamọran ni, ki o ma baa lo ọdun Keresimesi rẹ ninu irora. Mama ẹ wa labule, awọn ẹgbọn ati aburo rẹ ko tii jẹun, mama rẹ ko tii mọ nnkan to fẹẹ ṣe, sibẹ, iwọ n wa owo to maa fun obinrin ti o ko tii fẹ sile.
"Ṣe mo le fun ẹ lamọran? Bi ẹni kan ba n finna mọ ẹ loṣu kejila ti a wa yii, pa foonu ẹ, ki o si tan an pada loṣu kin-in-ni ọdun to n bọ, iyẹn bi o ko ba le mu mọra.
"O le tan foonu ẹ nigba ti o ba fẹẹ ba awọn to ṣe pataki sọrọ. Ma ṣe fun obinrin lowo lakooko ọdun Keresimesi ti a wa yii, tọju awọn mọlẹbi rẹ."
No comments:
Post a Comment