Kasnaty Sugar fi mọ́tọ̀ bọ̀gìnnì dá àgbà òṣèré tíátà, Túnbọ̀sún Ọdúnsì lọ́lá l'Abẹ́òkúta, ló bá bú sẹ́kún - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, December 13, 2021

Kasnaty Sugar fi mọ́tọ̀ bọ̀gìnnì dá àgbà òṣèré tíátà, Túnbọ̀sún Ọdúnsì lọ́lá l'Abẹ́òkúta, ló bá bú sẹ́kún


Bi wọn ba n sọ pe ọjọ wo ni inu agba ọjẹ nidii iṣẹ tiata nni, Alagba Tunbọsun Ọdunsi, ẹni tọpọ awọ eeyan tun mọ si Baba Amoye dun ju nigbesi aye, ọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kejila, oṣu kejila, ọdun 2021 tun ti kun awọn ọjọ naa, nitori pe ọjọ naa lo gba mọto ayọkẹlẹ lairo tẹlẹ.

Ilu Abẹokuta, ipinlẹ Ogun ni Tunbọsun Ọdunsi, ẹni to fẹran lati maa sunkun ninu fiimu agbelewo lọpọ igba ti gba mọto Toyota Camry, eyi ti awọn eeyan tun mọ si Big Daddy nibi eto kan ti gbajugbaja sọrọsọrọ nni, Ọgbẹni Kọlawọle Atanda Adejojo ṣe fawọn arugbo ni gbọngan ile itura Daktad to wa lagbegbe Quarry Road.

Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, wọn lo gba Kasnaty ni oṣu mẹfa gbako to ti n fẹẹ ri Alagba Ọdunsi, lati ṣe ifọrọwerọ pẹlu ẹ, ṣugbọn ti baba ẹni ọdun mọkandinlọgọrin naa ko daa lohun.


Wọn ni Dele Odule ti baba yii kọ niṣẹ tiata ti kọkọ baa sọrọ wi pe ko fun Kasnaty laaye lati jọ sọrọ, ṣugbọn ti ko dahun, ko to di pe ẹlomiran, iyẹn Tafa Oloyede tun baa sọrọ wi pe yoo ba ire bọ nibẹ.

Nigba to n sọrọ lori bi inu ẹ ṣe dun to nipa ẹbun tuntun yii, Ọdunsi sọ pe eyi ni yoo jẹ igbakeji toun yoo maa gba iru ẹbun bayii, nitori pe Afeez Ọwọ lo kọkọ fi ẹbun da oun lọla latigba toun ti bẹrẹ iṣẹ tiata.

“Ayọ mi kun debi pe mo fẹẹ ma mọ ohun ti mo le sọ, eyi lo di ẹlẹẹkeji tawọn eeyan n wo mi ṣunṣun lati ṣe loore. Afees Ọwọ lo ṣe ti akọkọ. Eyi to tun ya mi lẹnu ju ni pe awọ ọkọ ti a n wo lọjọ naa lọhun, eyi ti ko han si Afeez Ọwọ ni awọ ọkọ to gbe fun mi.

“Nigba ti a tun n ro ti eyi, awọ ọkọ ti a n ronu nipa rẹ, ti a si n wa kaakiri niluu Ibadan ni Kasnaty tun gbe fun mi l’Abẹokuta nibi. Ṣugbọn ohun to ya mi lẹnu nipa ti Kasnaty ni pe o wa mi fun odidi oṣu mẹfa gbako, ti mi o da lohun.



“Nigba ti mo maa wa daa lohun, Tafa Oloyede lo sọ pe ki n da ọkunrin yii lohun, ṣugbọn mo sọ pe awọn eeyan ti ṣe oriṣiriṣi fun mi to jẹ jẹ pe nigba ti wọn ba wa fọrọ wa mi lẹnu wo, kọọpu ti wọn fi n mu omi ni wọn maa fun mi, ṣugbọn Tafa Oloyede lo sọ pe ki n da Kasnaty lohun, wi pe maa ri ire nibẹ.

“Ohun to ya mi lẹnu ni pe nigba ti Kasnaty lọ gba ẹrọ ibanisọrọ mi lọwọ Dele Odule, to si wa mi kan. O ti n lọ bi ọwọ irọlẹ bayii lọjọ to ri mi, to si wọle mi wa. Mi o tiẹ mọ pe o mu awọn eeyan lẹyin lati ṣiṣẹ pẹlu ẹ. Ṣe lo da ọrọ silẹ wi pe oun ti ṣe wahala, oun ti n wa mi, wi pe ọpẹlọpẹ ọmọ yin Dele Odule lo foun ni nọmba lati pe mi.

“O n sọrọ nipa ile ti mo n gbe, mo wa jẹ ko yee wi pe inu igbo ni ile naa tẹlẹ. Mi o mọ pe wọn ti n ri kọọdu gbogbo ọrọ ti a jọ n sọ, awọn eeyan nilu Oyinbo, l’Amẹrika, ni Kanada ati kaakiri agbaye ti bẹrẹ sii da lohun lẹsẹkẹsẹ. Obinrin kan ti wọn n pe ni Adebutu lo kọkọ fi ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un naira ranṣẹ lọjọ naa. Ẹni kan naa ba tun fi ẹgbẹrun lọna aadọta naira ranṣẹ, ki n ma fa ọrọ gun, owo ti a ri jẹ ẹgbẹrun lọna irinwo le laadọta {450,000} naira.

“Bi wọn ṣe n pe lawọn eeyan ti n sọ pe ki n fi akanti mi sita, ki n to laju, owo ti bẹrẹ sii wọle. Taya mọto mi to dẹnukọlẹ ni Kasnaty kọkọ sọ pe ki awọn eeyan ra fun mi, ṣugbọn ẹsẹkẹsẹ lo sọ pe ki lo de ti a kọ le ra mọto fun baba yii, ere la kọkọ pee, ṣugbọn ti ere ọjọ naa ṣe di otitọ ree o.”


Loju ẹsẹ ni baba yii bẹrẹ awọn adura lọna inu ọkan rẹ, to si tun bu sẹkun bo ṣe maa n sunkun ninu fiimu agbelewo lọjọ naa.

Nibi eto ọhun lawọn arugbo mẹta kan to gbegba oroke ninu idije ijo jijo ti gba ẹbun ẹgbẹrun lọna aadọta naira, ẹgbẹrun lọna ọgbọn naira ati ẹgbẹrun lọna ogun naira. Awọn arugbo ti wọn ko le rin daadaa, ti ko din ni ogun ni wọn gba ọpa irinsẹ.

Ninu ọrọ tirẹ naa, Kasnaty sọ pe oun to tun ya oun lẹnu julọ ni pe nigba toun beere lọwọ Alagba Tunbọsun Ọdunsi wi pe iru nọmba wo ni yoo fẹ gba sinu ọkọ tuntun yii, wọn sọ pe nọmba ijọba ibilẹ Kọṣọfẹ l’Ekoo loun fẹ, ṣugbọn to tun jẹ mọ ti ajọ alaanu loun fẹẹ da silẹ ni baba yii beere, iyẹn Kasnaty Sugar Foundation, KSF.

Lara awọn to wa nibi eto ọhun ni Alagba Tafa Oloyede, Pa James Ajirebi, iya agbalagba ẹni ọgọfa ọdun, baba to bi Kasnaty, Alaaji Adejojo atawọn miran. Awọn agba akọroyin bii Alaaji Wumi Akinọla, Alagba Musilimu Arẹmu, Alagba Johnson Onifade, ati Alagba Dimeji Kayọde-Adedeji.




















No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI