L'ọgbọn ọjọ, oṣu kọkanla ti a ṣẹṣẹ lo tan yii, yẹn ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ana ni ijọba ipinlẹ Kwara tu aṣiri idi ti wọn fi fẹẹ kọ gbọngan nla agbaye, iyẹn International Conference Centre ti ko tii si iru rẹ ri silu Ilọrin.
Gomina AbdulRahman AbdulRazaq lakooko to n sọrọ nibi gbagede ipatẹ ọja agbaye, ẹlẹẹkẹjọ iru ẹ nipinlẹ Kwara, 8th Kwara State Joint Trade Fair to waye nilu Ilọrin, o ṣalaye lati le jẹ ki ipinlẹ naa di ohun tawọn onile-iṣẹ nla-nla yoo maa wọ lo fa a.
AbdulRazaq tẹsiwaju pe iṣakoso oun n gbiyanju lati wa gbogbo ọna ti eto ọrọ aje ipinlẹ naa yoo fi dagbasoke, nipa ṣiṣẹ opopona to ja geere, paapaa julọ gbogbo awọn nnkan to le mu kawọn olowo agbaye wọle lati da ileeṣẹ silẹ.
No comments:
Post a Comment