Ijọba ipinlẹ Kwara ti gbe igbimọ ti yoo ṣagbatẹru eto ọlọdọọdun, ẹlẹkeji iru rẹ, eyi ti wọn fi n ṣe igbelarugẹ awọn ounjẹ to ṣe ara loore, iyẹn Nutritious Food Fair to fẹẹ waye loṣu kejila ti a wa yii.
Igbimọ naa ti wọn pe ni Local Organising Committee (LOC), la gbọ pe wọn yoo ri si bi eto ọdun yii yoo ṣe larinrin, ti yo si ni ipa rere nigbesi aye awọn araalu.
Ọjọ kẹẹdogun si ọjọ kẹrindinlogun, oṣu kejila, ọdun 2021 ti a wa yii la gbọ pe eto naa yoo waye ni gbọngan ijọba, iyẹn State Government Banquet Hall, to wa ni adojukọ ilegbe awọn gomina, nilu Ilọrin, ipinlẹ naa.
Nigba to n sọrọ nipa ọna ti wọn yoo gbe ayẹyẹ tọdun yii gba, alaga igbimọ ọhun, Malaamu Abdulquawiy Olododo gba gbogbo awọn ọmọ igbimọ lamọran lati fọwọsowọpọ, ki wọn si ṣiṣẹ papọ lati rii pe wọn ṣe aṣeyọri to lọọrin, kọja ti atẹyinwa.
No comments:
Post a Comment