Ileeṣẹ to n ri sọrọ ere idaraya nipinlẹ Kwara ti rawọn ẹbẹ sawọn araalu loir awuyewuye to n lọ kaakiri igboro wi pe papa isere tipinlẹ naa ti bajẹ kọja sisọ, ati pe wọn tun ti n lo o lati fi ṣe oniruuru ayẹyẹ.
Wọn ni lotitọ, papa iṣere naa ti nilo atunṣe lati oṣu kin-in-ni, ọdun 2021 ti a wa yii, ṣugbọn ti ijọba ipinlẹ naa ko tete kọbi ara sii, ti wọn si jẹ ko di mimọ pe laipẹ ni atunṣe yoo bẹrẹ.
Ninu atẹjade ti Abdullahi Yunusa Lade gbe jade lati ileeṣẹ to n ri sọrọ ere idaraya nipinlẹ ọhun, o jẹ ko di mimọ pe owo ti wọn yoo fi tun papa iṣere naa ṣe ti wa ninu eto iṣuna ọdun 2022 to n bọ lọna yii.
Laipẹ yii ni awọn awuyewuye kan jade lori papa iṣere naa wi pe wọn ti n lo agboorun {canopy}lori papa iṣere yii, ati pe yoo fẹẹ to ọdun 2023 ko to di pe wọn bẹrẹ sii lo papa iṣere fun awọn idije tabi ifigagbaga to ba ṣe pataki.
Ileeṣẹ to n ri sọrọ ere idaraya wa jẹ ko di mimọ pe aaarin ọṣu mẹfa akọkọ lọdun to n bọ ni atunṣe ọhun yoo waye, ki gbogbo awọn eeyan lọ fọkan balẹ.
No comments:
Post a Comment