Oloye Olumide Aderinokun, Akinruyiwa tilu Owu Abẹokuta ti mu ileri rẹ ṣẹ fun gbogbo awọn to padanu dukia ati ọja wọn sinu ijamba ina to ṣẹyọ lọsẹ to kọja lọ lọhun.
Bẹ o ba gbagbe, ọjọ Aiku tii ṣe Sannde meji sẹyin ni tanka elepo nla kan ṣubu nibi oju irin reluwee to wa ni Lafẹnwa, ijọba ibilẹ Ariwa Abẹokuta, ipinlẹ Ogun.
Ọjọru, Wẹside ọsẹ to kọja ni Oloye Olumide Aderinokun, ẹni to tun jẹ ọkan lara awọn agba ninu ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP nipinlẹ naa ṣe abẹwo ibanikẹdun sibi ijamba ina ọhun.
Nibẹ lo ti ba awọn to padanu dukia ati ọja wọn kẹdun, to si tun ba Iyalọja ati Babalaje ṣe ipade, nibi to ti ṣe ileri lati fun awọn ọlọja aadọta ni owo ti ko din lẹgbẹrun lọna aadọta naira, gẹgẹ bi owo iranwọ.
Ọjọbọ, Tọside, ana ni Oloye Aderinokun pẹlu ikọ akọwọrin rẹ pada si ọja Lanfẹnwa ọhun lati mu ileri rẹ ṣẹ fun wọn.
Pupọ awọn to jẹ anfaani yii ni wọn dupẹ lọwọ ọkunrin naa, ti wọn si lawọn ṣetan lati ṣe iranlọwọ to ba yẹ fun un lakooko idibo to n bọ lọna.
Nigba to n sọrọ, Aderinokun sọ pe ki gbogbo awọn obi ati alagbatọ lọ sọ fawọn ọmọ wọn lati tete lọ fi orukọ silẹ funa kaadi idibo ko to to akoko lati le dibo fun awọn ẹlẹyinju aanu.
No comments:
Post a Comment