Awọn agbaagba ati alẹnulọrọ ninu ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress (APC), nipinlẹ Ọṣun ti sọ pe adanu nla ni yoo jẹ fun ẹgbẹ naa, bi wọn ba tun yan Adegboyega Oyetọla lati jade du ipo naa lẹẹkeji, nitori pe ipo naa yoo bọ mọ wọn lọwọ ni., the incumbent governor.
Bkan naa ni wọn sọ pe awọn ti ṣetan lati fọwọsowọpọ, ki wọn le gba ipinlẹ naa kuro lọwọ iwolulẹ ati pajude, ati ipadanu ibo, ko to pẹ ju.
Nigba ti wọn n sọrọ nibi anakṣe eto ipade awọn The Osun Progressives (TOP), iyẹn ti igun ẹgbẹ APC l'Ọṣun, igbakeji olori ile igbimọ aṣofin ana, Lasun Yusuff; olori ile igbimọ aṣofin tẹlẹriri, Najeen Salam ati akọwe ijọba ipinlẹ naa tẹlẹri, wọn kọminu lori bi Gomina Oyetọla ṣe n fi oṣelu ba wọn ṣe papọ, eyi to ti mu iyapa ati aiṣọkan ba wọn ni ninu ẹgbẹ latigba to ti de ijọba lọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu kọkanla, ọdun 2018.
Awọn mẹtẹẹta yii ti wọn ti du ipo naa pẹlu Oyetọla lọdun 2018, ti wọn si tun n foju sọna lati du ipo naa pada lọdun 2022, ni wọn ti gba bayii lati jọ ṣiṣẹ papọ, ki wọn le bori.
Wọn lawọn ti ṣetan bayii, lati fọwọsowọpọ pẹlu eyikeyi ninu wọn to ba pada wọle gẹgẹ bi oludije lọdun 2022, ki wọn le rii pe wọn bori ninu idibo ọhun.
No comments:
Post a Comment