Idaniloju to peregede ti wa bayii wi pe ẹwọn lawọn gendekunrin meji ti ẹ n wo oju wọn yii yoo ti ṣayẹyẹ ọdun Keresimesi to n bọ lọna yii, lori mọt onimọto ti wọn jigbe l'Ekoo.
AWIKONKO gbọ pe ipinlẹ Eko lawọn mejeeji naa, Kenneth Akpa ati Adebayọ Michael ti digun gba mọto Toyota Corolla, ṣugbọn agbegbe Ogere si Ipẹru, nipinlẹ Ogun lọwọ palaba wọn ti segi.
Mọto naa ti nọmba idanimọ rẹ jẹ MUS 599 GV la gbọ pe wọn digun gba lọwọ James John Ushahemba to n gbe lagbegbe Ahoyaya nipinlẹ Eko ni nnkan bi agogo kan aabọ oru l'ogunjọ, ọsu yii, iyẹn ọjọ Aje, Mọnde, ana.
Ọgbẹni James la tun gbọ pe lẹyin ti wọn gba mọto naa lọwọ ẹ, wọn tun fi ibọn gba foonu olowo nla mẹta ọtọọtọ, to fi mọ ẹgbẹrun lọna ọgbọn naira naira lọwọ ẹ, ko to di pe wọn na papa bora.
Bi ilẹ ṣe mọ la gbọ pe ọkunrin naa gba teṣan ọlọpaa lọ lati fi to wọn leti, ti iṣẹ iwadii si bẹrẹ lẹkunrẹrẹ. Lakoko ti iwadii n lọ lọwọ la gbọ pe wọn kofiri mọto ọhun ninu ọgba ibi tawọn mẹkaniiki ti n ṣiṣẹ nilu Ipẹru.
Loju ẹsẹ lawọn mẹkaniiki naa ti tọka sawọn to gbe e wa, ti wọn si ko awọn mejeeji yii.
Ọga ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Lanre Bankọle ti paṣẹ pe ki iwadii tubọ tẹsiwaju lori awọn mejeeji, ko to si pe wọn ko wọn lọ s'Ekoo, nibi ti iwadii yoo tun ti bẹrẹ lori wọn, ti wọn yoo si foju ba ile-ẹjọ.
No comments:
Post a Comment