Ariwo ikunlẹ abiyamọ lo gba ẹnu ọpọ awọn eeyan lonii, ọjọ Aje, Mọnde nigba ti ijamba mọto fẹmi eeyan kan ṣofo danu, ti awọn mejidinlogun si farapa yannayanna, nipinlẹ Ọṣun.
Ẹnu ọna abawọle si ọgba awọn oṣiṣẹ ti Abere, to wa nilu Oṣogbo, ipinlẹ naa la gbọ pe ijamba yii ti waye ni nnkan bi agogo meji ku iṣẹju mẹẹdogun ọsan.
Wọn ni mọto Toyota Hiace, alawọ funfun ti nọmba idanimọ rẹ jẹ EKY 213 XP, lo kagbako ijamba yii funra rẹ.
Awọn oṣiṣẹ oju popona ti FRSC, la gbọ pe wọn ko gbogbo wọn lọ si ọsibitu LAUTECH, to wa nilu Osogbo, fun itọju, ti wọn si wọ mọto naa lọ si teṣan ọlọpaa to wa ni Dugbẹ.
No comments:
Post a Comment