Ẹ wo ojú Victor tó n fi orúkọ Sound Sultan lu jìbìtì lẹ́yin ikú ẹ̀ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Sunday, December 5, 2021

Ẹ wo ojú Victor tó n fi orúkọ Sound Sultan lu jìbìtì lẹ́yin ikú ẹ̀


Ọwọ ileeṣẹ ọlọpaa ti tẹ gendekunrin kan ti wọn pe orukọ rẹ ni Victor Majẹkodunmi, ẹni ti wọn lo n gbiyanju lati maa fi orukọ ogbontarigi olorin nni, Sound Sultan to doloogbe loṣu keje ọdun yii lu jibiti lori ayelujara.
 
AWIKONKO gbọ pe ṣe ni Victor gba ikanni ayelujara ti Instagiraamu to jẹ ti oloogbe naa, to si pa gbogbo awọn akọsilẹ rẹ nibẹ, eyi ti wọn lo fẹ maa fi lu jibiti.
 
AWIKONKO gbọ pe bi aṣiri yii ṣe tu si awọn mọlẹbi oloogbe naa lọwọ, ni wọn ti lọ fi to ileeṣẹ ọlọpaa leti, ta a si gbọ pe loju ẹsẹ ni wọn ti bẹrẹ iṣẹ iwadii wọn.
 
Ko pẹ rara ti a gbọ pe ọwọ fi tẹ Victor, ẹni ti wọn lo ti n pe ara rẹ ni Farida, iyawo oloogbe, to si n sọ pe awọn atunṣe kan fẹẹ waye.
 
Aburọ Sound Sultan, Baba Dee nigba to n fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ sọ pe ọwọ ti tẹ Victor, ogbologbo oni jibiti naa, to si ti n gbadun ara rẹ lahamọ awọn agbofinro.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI