Dàpọ Abíọ́dún yóò sáré kàbàkàbà, ìwọ́dé tí yóò dá ìjọba Buhari dúró fún wákàtí mẹ́rin nbọ̀ lọ́dún 2022 - Wòlíì Ayọ̀délé ju bọ́mbù àsọtẹlẹ síta - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, December 20, 2021

Dàpọ Abíọ́dún yóò sáré kàbàkàbà, ìwọ́dé tí yóò dá ìjọba Buhari dúró fún wákàtí mẹ́rin nbọ̀ lọ́dún 2022 - Wòlíì Ayọ̀délé ju bọ́mbù àsọtẹlẹ síta


Lonii, ọjọ Aje, Mọnde, ogunjọ, ọsu kejila, ọdun 2021 ni alaṣẹ ati oludasilẹ ṣọọṣi INRI Evangelical Spiritual Church, Wolii Elijah Ayọdele tun ju bọmbu asọtẹlẹ sita nipa Gomina ipinlẹ Ogun, Ọmọọba Dapọ Abiọdun; Aarẹ Mohammadu Buhari; iyawo Aarẹ Buhari, Aisha Buhari fọdun 2022.
 
Ninu atẹjade asọtẹlẹ naa ti akọwe iroyin Wolii Ayọdele, Ọgbẹni Oluwatosin Ọṣhọ gbe jade lonii, lo ti sọ pe Gomina Dapọ Abiọun tipinlẹ Ogun yoo sare kabakaba lọdun 2022 nitori ọna lati ri tikẹẹti lati pada sipo gomina lẹẹkeji gba.
 
Bakan naa lo sọ pe iwọde ifẹhonu han nla ti yoo mi ijọba Buhari titi yoo tun ṣẹlẹ lọdun 2022, to si ni fun bii wakati mẹrin gbako ni nnkan ko fi nii lọ deede.

Siwaju sii lo tun sọ pe idaamu yoo de ba iyawo Aarẹ, iyẹn Aisha Buhari.
 
Wolii Ayọdele tun jẹ ko di mimọ pe wọn yoo ji ọga agba ologun kan gbe lorilẹ-ede yii.

Ninu atẹjade naa, Wolii Ayọdele sọ pe “Gomina ipinlẹ Ogun, Ọmọọba Dapọ Abiọdun yoo sare kabakaba lọdun 2022. Wọn maa ji ọga agba ologun gbe.

“Iwọde ifẹhonuhan nla miran ti yoo da ijọba Aarẹ Buhari duro fun wakati mẹrin gbako yoo ṣẹlẹ. Ẹ jẹ ka gbadura ka ma ṣe padanu ọga ọlọpaa lorilẹ-ede yii.

“Ọlọpaa Naijiria ati awọn ologun yoo da iṣẹ silẹ. Idaamu yoo de ba Aisha Buhari.”

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI