Afárá Mòró tó já lulẹ̀: Àwọn aráàlú rawọ́ ẹ̀bẹ̀ s'íjọba àpapọ̀ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Sunday, December 5, 2021

Afárá Mòró tó já lulẹ̀: Àwọn aráàlú rawọ́ ẹ̀bẹ̀ s'íjọba àpapọ̀


Awọn ara ati olugbe ilu Moro to wa nijọba ibilẹ Ariwa Kwara ti rawọ ẹbẹ si ijọba apapọ lori afara ilu Moro to fẹẹ ja lulẹ lojiji, eyi ti ko jẹ ki igbokegbodo ọkọ lọ bo ṣe yẹ, koda, to tun fa ọwọ aago idagbasoke eto ọrọ aje sẹyin.

Wọn ni diẹ lo ku ki afara naa ja lulẹ, eyi to ṣee ṣe mu ẹmi awọn araalu lọ, bi ijọba apapọ ko ba tete wa nnkan ṣe sii, paapaa ati pe ki wọn tii pa fun igba diẹ ti atunṣe yoo fi waye

AWIKONKO gbọ pe ijoba ipinelẹ Kwara ti dide nigba kan ri lati ṣe atunṣe afara yii, ṣugbọn ti wọn sọ pe ijọba papaọ, iyẹn ileeṣẹ to n ri sọrọ atunṣe opopona kaakiri da wọn lọwọ kọ, nitori ti wọn ni iṣẹ ijọba apapọ ni, kii ṣe tipinlẹ.

Nigba ti wọn n sọrọ, ẹgbẹ awọn nilu Moro, iyẹn Moro Youths Association, sọ pe ki ijọba apapọ tete wa a ti afara ọhun pa, lati tete wa ọna abayọ ti wọn n koju lori afara naa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI