Lọsẹ to kọja yii ni Gomina AbdulRahman AbdulRazaq tipinlẹ Kwara fa ile-ẹkọ ti wọn ti n kẹkọọ nipa iṣẹ ọlọpaa, eyi ti wọn ṣẹṣẹ ṣe atunṣe rẹ pari le ileeṣẹ ọlọpaa lọwọ.
Ile-ẹkọ naa, Ballah Police School, to wa nijọba ibilẹ Asa la gbọ pe o ti dẹnnukọlẹ lati bi ọpọlọpọ ọdun sẹyin, eyi to n wa ọwọ agogo ikẹkọọ sẹyin nibẹ, koda, ti wọn ni ilana eto ẹkọ nibẹ ko ba ti igbalode mu.
Eyi lo jẹ ki Gomina AbdulRahman pinnu lati ṣe atunkọ rẹ, fawọn araalu lati ni imọlara ọhun ti wọn n pe ni eto iṣejọba awaarawa, paapaa lẹka eto ẹkọ.
Nigba to n sọrọ lakooko to n fa ile-ẹkọ naa le ileeṣẹ ọlọpaa, ati ileeṣẹ to n ri sọrọ eto ẹkọ nipinlẹ Kwara lọwọ, AbdulRazaq sọ pe lara awọn ipinnu oun lọdun 2019, paapaa lori ọrọ eto ẹkọ lo tun wa si imuṣẹ.
O ni lara awọn nnkan to jẹ oun logun julọ ni eto ẹkọ, nitori pe awọn eeyan gbọdọ mọ bi nnkan ṣe n lọ lagbaye, ati pe ilana eto ẹkọ ipinlẹ ọhun gbọdọ lọ ni ibamu pẹlu ti igbalode ti wa yii.
No comments:
Post a Comment