Wọ́n tún ti jí Baálẹ̀ gbé l'Òndó o - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, November 23, 2021

Wọ́n tún ti jí Baálẹ̀ gbé l'Òndó o


Awọn agbebọn kan la ti gbọ bayii pe wọn ti ji olori awọn ẹya Ibo gbe nilu Ondo, ti ko si tii sẹni to le sọ pato ibi ti awọn agbebọn naa ti wa, ati ibi ti wọn gbe e lọ.
 
Baalẹ awọn Ibo, iyẹn Eze Ndigbo to wa nilu Afọn, ijọba ibilẹ Oṣe nipinlẹ Ondo, Oloye Donatus Okereke, ẹni ti wọn loo gbajumọ daadaa ninu okoowo ṣiṣe laaarin ilu naa la gbọ pe ko tii sẹni to le sọ pato ibi to wa titi di asiko ti a pari akojọpọ iroyin yii.
 
Agbegbe ti a gbọ pe wọn ti ji Oloye Okereke gbe naa ni wọn pa Oba ilu Ifọn, Oba Israel Adeusi si lọdun to kọja, gẹgẹ bi a ṣe gbọ.
 
Lara awọn to fi iroyin ọhun to wa leti sọ pe ṣe lawọn agbebọn to jii gbe yinbọn soke, ko to di pe wọn gbe e salọ. Koda, akọwe si adele ọba ilu Ifọn, Olaniyi Eni Olotu, fidi iṣẹlẹ yii mulẹ.
 
Olotu lo jẹ ko ye wa pe awọn ọlọpaa ati awọn oṣiṣẹ eleto aabo ti Amọtẹkun ti bẹrẹ iṣẹ iwadii, ati pe awọn agbebọn naa tun gbe obitibiti owo salọ ninu mọto ọkunrin naa.
 
Funmilayo Ọdunlami, to jẹ agbẹnusọ fawọn ọlọpaa ipinlẹ Ondo sọ pe ẹgbẹ ọna ni wọn ti ri mọto Okereke, ti wọn ko si tii rii ba sọrọ, ṣugbọn to sọ pe iwadii ti n lọ lọwọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI