Wọ́n ti rí òkú àbúrò Kábíyèsí tí wọ́n jígbé ní Kwara - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, November 25, 2021

Wọ́n ti rí òkú àbúrò Kábíyèsí tí wọ́n jígbé ní Kwara


Ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Kwara ti jẹ ko di mimọ pe awọn ti ri oku Olulaja Adegbọla, aburo Kabiyesi ilu Ọlla to wa nijọba ibilẹ Isin nibi ti wọn jigbe lọjọsi.

Ọjọ Ẹti, Furaide, ọsẹ to kọja yii la gbọ pe wọn ji Adegbọla, ẹni tọpọ awọn eeyan tun mọ si Onijay gbe nilu Ọlla.

AWIKONKO gbọ pe aburo ni Onijay tun jẹ si ọkan lara awọn oloye ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party (PDP), Ọnọrebu Onijala, ẹni to tun jẹ ọkan lara awọn alabaṣiṣẹ pọ Aarẹ ana lorilẹ-ede yii, Goodluck Ebele Jonathan.

Police recover decomposing body of kidnapped Kwara monarch 
Wọn ni inu oko ti Oni-jay da lo ti n bọ lọjọ naa, ko to di pe wọn daa lọna ninu mọto Hilux rẹ, ti wọn si dabọn bo o, ko to di pe wọn jii gbe salọ, ti wọn si n beere miliọnu lọna igba naira, ṣugbọn ti wọn sọ pe awọn yoo gba miliọnu mẹwaa naira.

Ọkasanmi Ajayi, alukoro ileeṣẹ ọlọpaa sọ pe inu igbo lawọn ti ri oku Onijay lakooko tawọn n wa ọna bi wọn yoo ṣe rii gba jade kuro lọwọ wọn lai farapa, lai mọ pe wọn ti pa a.

Police recover decomposing body of kidnapped Kwara monarch

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI