Arabinrin Ọmọlara Ọlatubọsun, to jẹ iya Ọmọọbabinrin Adeọla Ogunwusi ti pariwo sita wi pe Ọọni Ile-Ifẹ, Ọba Adeyẹye Ẹnitan Ogunwusi ko mọ nnkankan nipa bi ọmọ naa ṣe dagba, nitori pe ko gba a gẹgẹ bi ọmọ nigba toun bii tan.
Ọmọlara to bimọ akọkọ fun Ọba Ogunwusi nigba to wa lọmọ ọdun mọkandinlogun lo sọrọ naa lati tako ọrọ Ọọni to kọ sori ikanni ayelujara wi pe ṣe loun da ọmọ naa tọ titi to fi dagba, ṣugbọn ti obinrin naa sọ pe irọ to jinna si otitọ ọrọ ni.
Nigba to n sọrọ, Ọmọlara sọ pe gbara toun ti loyun fun Ọba Ogunwusi lo ti le oun danu, to si loun kọ loun loyun naa, ṣugbọn to loun gba kadara wi pe Ọlọrun yoo ba oun tọ ọmọ naa.
Bẹ o ba gbagbe, ọjọ kejidinlogun, oṣu kẹwaa, ọdun yii ni Ọba Adeyẹye Ogunwusi gbe fọto oun pẹlu Ọmọọbabinrin Adeọla sọri ikanni ayelujara, nibi to n kii ku oriire ayẹyẹ ọjọ ibi rẹ, to si jẹ ko ye gbogbo aye wi pe ko rọrun lati da tọ ọmọ naa lati kekere titi to fi dagba.
Ninu ọrọ Ọmọlara, o sọ pe nigba ti Ọba Ogunwusi maa kọkọ ri ọmọ naa, ọsibitu ni, lẹyin toun bii tan. O ni lẹyin eyi ni Ọọni Ifẹ ko yọju mọ, ko to tun di pe awọn pade lẹyin ọdun kẹrin, nigba to wa bẹ oun lati jẹ kọmọ naa lọ ṣe ọmọ iyawo fun ẹgbọn rẹ to ṣe igbeyawo nigba naa.
Ọmọlara tẹsiwaju pe fun ọdun mẹwaa akọkọ ni Ọọni ko mọ ohunkohun nipa igbe aye ọmọ rẹ, ko to jẹ pe nigba tọmọ naa pe ọmọ ọdun mẹtala lawọn eeyan bẹ oun lati jẹ ko maa lọ sọdọ baba rẹ lati ṣe ọlude nibẹ.
Bẹẹ lo sọ pe nigba ti Adeọla pe ọmọ ọdun mẹẹdogun lo di pe o ṣẹṣẹ bẹrẹ sii lọ gbe lọdọ baba rẹ.
Adeọla funra rẹ ti wa sọ pe oun ko ni ohunkohun lati sọ lori ọrọ naa nitori pe oun ko fẹran lati maa wa loju iwe iroyin kaakiri..
No comments:
Post a Comment