Wọ́n ju olùkọ́ Kwasu sátìmọ́lé lórí ẹ̀sun ìdúnkoòkò láti bá akẹ́kọ̀ọ́ láṣepọ̀ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, November 10, 2021

Wọ́n ju olùkọ́ Kwasu sátìmọ́lé lórí ẹ̀sun ìdúnkoòkò láti bá akẹ́kọ̀ọ́ láṣepọ̀


Ile-ẹjọ Majisirreti tilu Ilọrin, lọjọ Iṣegun, Tuside ana, ti sọ ọkunrin kan, Pẹlumi Adewọle si atimọle lori ẹsun wi pe o n gbimọ lati fipabanilopọ, aṣemaṣe ninu idanwo ati idunkoko mọ akẹkọọ.
 
Ọkan lara awọn olukọ fasiti ipinlẹ Kwara, iyẹn Kwara State University, to wa lagbegbe Malete ni wọn pe Pẹlumi, awọn agbofinrin ọtẹlẹmuyẹ ti wọn pe ni State Intelligence Bureau, SIB lo rọwọ to ọkunrin naa, gẹgẹ bi a ṣe gbọ.

Ẹsun ti wọn si ka sii lẹsẹ la gbọ pe o tako iwe ofin ọdaran ti abala 397, 95, iyẹn Penal Code Law, ati abala 3(320) ti Examination Malpractices Act CAP E 15 Law tijọba apapọ orilẹ-ede Naijiria.
 
Bo tilẹ jẹ pe ile-ẹjọ naa labẹ akoso Onidajọ Ibrahim Mohammed faaye silẹ fun beeli Pẹlumi pẹlu ẹgbẹrun lọna igba naira, sibẹ wọn ni ko tii sẹni to le duro fun un titi di asiko ti a pari akojọpọ iroyin yii.
 
AWIKONKO gbọ pe akẹkọọ kan, Adegunsoye Faith Tosin ti ẹka ikẹkọọ Pure and Applied Science ni fasiti naa lo fẹsun kan Pẹlumi lọjọ kẹẹdogun, oṣu kẹwaa, ọdun yii.
 
Ninu iwe ẹsun naa lo ti sọ pe laaarin ọsu kẹsan-an, ọdun yii ni wọn gbe Pẹlumi wa lati kọ wọn ni ẹkọ MLS 212 Cell ati Molecular Biology. O nigba ti wọn gbe e wa, lo ṣalabapade oun, to si n dunkoko lati jẹ koun kuna ti ko ba gba kawọn jọ ni ibalopọ.
 
Idunkoko naa lo jẹ ko lọ fọrọ ọhun to awọn ọlọpaa leti, ti wọn si ni koun naa fọgbọn ṣe e, ki aṣiri baa le tu. Si iyalẹnu, wọn ni ṣe ni Pẹlumi tan akẹkọọ naa sinu yara rẹ nile to n gbe, ni nnkan bi aago mẹjọ aabọ lati ba a laṣepọ.

Nibẹ lo si ti tun ti fun un lawọn ibeere to wa ninu idanwo ti wọn ṣe, ati iwe idahun ibeere lati tun idanwo naa kọ, pẹlu ileri lati baa laṣepọ titi tilẹ yoo fi mọ.
 
Ibi ti wọn ti n fa ọrọ yii lọwọ ni wọn lawọn ọlọpaa naa ti wọle, ti wọn si mu. Ọjọ kẹjọ, oṣu kejila, ọdun yii ni igbẹjọ yoo tun tẹsiwaju.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI