Ọwọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti tẹ gendekunrin kan, ọmọ ẹgbẹ okunkun kan, Esuruoṣo Tunde, ẹni ti wọn lo digun lọ ka wọn mọ otẹẹli LADIS to wa ni ikorita Ebenezer, agbegbe Ọbantoko nilu Abẹokuta, ipinlẹ Ogun.
AWIKONKO gbọ peawọn ara otẹẹli naa ni wọn ranṣẹ pe awọn ọlọpaa ẹkun Ọbantoko wi pe awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun ti yawọ ọdọ wọn, ti wọn si ti n da wahala silẹ.
Eyi lo jẹ kawọn ọlọpaa naa gbera lati sare lọ sibẹ, ti wọn si lọ koju wọn. Nibi ti wọn ti n yẹ gbogbo ayika otẹẹli ọhun wo ni wọn ti ba ibọn lọwọ Tunde.
Loju ẹsẹ lo ti n bẹbẹ pe ki wọn ṣe oun jẹjẹ, nitori lotitọ loun jẹ ọmọ ẹgbẹ okunkun Ẹiyẹ.
O ni ọga awọn to ko wọn wa lo fa ibọn naa le oun lọwọ ko to na papa bora, ati pe oun ko mọ pe wahala lawọn fẹ wa fa nibẹ nigba tawọn n bọ.
Ni bayii, ọga ọlọpaa, Lanre Bankọle ti wa paṣẹ pe ki wọn lọ ṣe iwadii Tunde daadaa, ko to di pe wọn foju rẹ ba ile-ẹjọ.
No comments:
Post a Comment