Gbogbo ọjọ kejilelogun, oṣu kọkanla ọdun ni ayajọ ayẹyẹ ọjọ ti wọn bi gbajugbaja akọroyin nni, Arabinrin Toyin Agbọlade, ẹni tọpọ awọn eeyan mọ si Irọn Lady.
Lagboole akọroyin lorilẹ-ede Naijiria, paapaa nipinlẹ Eko ati Ogun, odu ni Toyin Elizabeth Agbọlade, Olootu-binrin {Woman Editor} Iwe iroyin Yoruba nni, ALARIYA OODUA, kii ṣaimọ foloko.
Agbọlade,, ẹni to tun jẹ ọkan lara awọn ololufẹ IROYIN AWIKONKO la gbọ pe awọn ololufẹ rẹ ti n fi atẹjiṣẹ ati ẹbun oriṣiriṣi ranṣẹ sii lati nnkan bi ọsẹ meji sẹyin ti ọjọ ibi rẹ ti n bọ lọna.
Bi ọpọ awọn eeyan lagbaye ṣe n ba Toyin Agbọlade yọ ayọ ọjọ ibi rẹ, naa ni gbogbo awọn alaṣẹ ati oṣiṣẹ ileeṣẹ AWIKONKO MEDIA CHANNEL to n gbe iroyin AWIKONKO jade naa n ki akikanju akọroyin yii ku oriire.
Adura wa ni pe wa a ṣe ọpọ ọdun laye ninu ọla nla, ninu irọrun, ifọkanbalẹ ati oore ọfẹ Ọlọrun ti ko wọpọ. Amin.
No comments:
Post a Comment