Sulaiman tó jí jẹnẹrétọ̀ gbé n'Ílọrin ti há o - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, November 12, 2021

Sulaiman tó jí jẹnẹrétọ̀ gbé n'Ílọrin ti há o


Kani kii ṣe pe awọn fijilante nilu Ilọrin, ipinlẹ Kwara ko figba kankan tura silẹ ni, boya ni gendekunrin tọwọ tẹ yii lakooko to lọ ji jẹnẹretọ gbe nile onile ti raaye na papa bora.
 
Gẹgẹ bi agbẹnusọ ileeṣẹ Sifu Difẹnsi nipinlẹ naa, Babawale Afọlabi ṣe ṣalaye fawọn akọroyin, o sọ pe ile kan to wa ni Oke Fọma Phase 3 Estate ni Abdulwasiu Sulaiman, ọmọ ọdun mọkanlelogun naa ti lọ ji jẹnẹretọ ọhun gbe.
 
Afọlabi jẹ ko ye wa pe lati ọsẹ meloo kan sẹyin lawọn adigunjale ti n jale lagbegbe naa, ti wọn si n ji dukia awọn eeyan gbe loriṣiriṣi.
 
O ni ṣe ni Sulaiman fo fẹnsi ile ẹni kan ti wọn pe ni Moshood Otubu wọle, to si ji jẹnẹretọ ti owo rẹ ko din ni ẹgbẹrun lọna aadọjọ naira gbe.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI