Lonii, Ọjọru, Wẹside, ọjọ kẹta, oṣu kọkanla ni idunnu tun ṣubu lu ayọ awọn ọmọ ati olugbe ipinlẹ Kwara lori bi awọn ti ko din ni ẹgbẹrun lọna ọgbọn tun ṣe jẹ anfaani ẹyawo ọfẹ ti wọn pe ni Owo Iṣowo.
Ẹyawo naa la gbọ pe ko ni ele kankan lori, pẹlu erongba lati jẹ ki eto ọrọ aje ipinlẹ naa dagbasoke, ki iṣẹ ati oṣi si le dinku lawujọ ipinlẹ naa.
Nigba to n sọrọ, Gomina AbdulRahman AbdulRazaq sọ pe eto tawọn gbe kalẹ yii, awọn ti ko din ni ẹgbẹrun lọna ọgọta ni wọn ti jẹ anfaani naa laaarin ọdun to kọja si ọdun yii.
O jẹ ko di mimọ pe pupọ awọn to ti jẹ anfaani eto ẹyawo Owo Iṣowo ati Owo Arugbo to wa nita naa ti ko ni ele ninu yii ni wọn jẹ ida aadọrun-un.
O ni fun idagbasoke eto ọrọ aje ati iranlọwọ fawọn arugbo ni wọn ṣe gbe eto na kalẹ, ati paapaa lati din iṣẹ ati oṣi ku lawujọ.
No comments:
Post a Comment