Iroyin to tẹ AWIKONKO lọwọ laipẹ yii ti fi ye wa pe ẹnikan ti gun gbajugbaja sọrọ ori redio nni, David Ekanem pa lopin ọsẹ to ṣẹṣẹ kọja yii.
Opopona marosẹ Murtala Mohammed to wa nilu Calabar, ipinlẹ Cross River la gbọ pe iṣẹlẹ ọhun ti waye ni nkan bi aago mẹwaa owurọ, ọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kẹfa, oṣu yii.
A gbọ pe odu ni David Ekanem, kii ṣaimọ foloko lagboole sọrọsọrọ, koda, ti wọn ni ede Ẹfik lo fi maa ṣeto fawọn ololufẹ rẹ lori redio FAD FM to wa nilu Calabar.
Wọn ni titi di asiko ti a ṣakojọpọ iroyin yii tan ni ko tii sẹni to le sọ patọ ẹni to gun ọkunrin tọpọ awọn eeyan tun mọ si Itiat Zion pa
Bakan naa la gbọ pe iwadii awọn ọlọpaa ti n lọ lori iṣẹlẹ ọhun, koda, agbẹnusọ fawọn ọlọpaa, Irene Ugbo lawọn ti gbọ sii, ati pe awọn ti bẹrẹ ofintoto wọn.
No comments:
Post a Comment