Ǹńkan ṣe! Wọ́n fẹ̀sun jìbìtì kan Obi Cubana, àhámọ́ EFCC ló wà láti àná - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, November 2, 2021

Ǹńkan ṣe! Wọ́n fẹ̀sun jìbìtì kan Obi Cubana, àhámọ́ EFCC ló wà láti àná


Titi di asiko ti a ṣakojọpọ iroyin yii tan ni gbajugbaja olowo nni,
Obinna Iyiegbu, ẹni tọpọ awọn ololufẹ rẹ mọ si Obi Cubana ṣi wa lahamọ awọn ajọ to n gbogun ti iwa jibiti ati ajẹbanu, Economic and Financial Crimes Commission (EFCC) nilu Abuja.
 
Aago mejila, ọsan ana, ọjọ Aje, Mọnde la gbọ pe Obi Cubana de ileeṣẹ EFCC to wa lagbegbe Jabi, nilu Abuja, nibi ti wọn ti n fọrọ wa a lẹnu wo lasan ni.
 
Lati oṣu keje, ọdun yii la gbọ pe awọn EFCC ti n foju sọna lati ranṣẹ pe Obi Cubana, iyẹn lẹyin to ṣe oku mama rẹ, nibi ti wọn ti ba owo ninu jẹ.
 
EFCC lawọn fẹ ko wa a ṣalaye ibi to ti ri aduru owo to na lọjọ ayẹyẹ oku mama rẹ, gẹgẹ ba a ṣe gbọ.
 
Wilson Uwujaren, to jẹ agbẹnusọ fun ajọ EFCC, sọ pe oun ko si lẹnu iṣẹ nigba ti Obi Cubana de ọdọ wọn, to si loun ko le sọrọ lori rẹ. O ni lẹyin iwadii, loun yoo to ṣẹṣẹ sọrọ sita.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI