Nítorí Kanu, wàhálà àti ìdààmú tuntun dé bá Obi Cubana, àwọn agbébọn IPOB ló n fikú waa káàkiri - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, November 12, 2021

Nítorí Kanu, wàhálà àti ìdààmú tuntun dé bá Obi Cubana, àwọn agbébọn IPOB ló n fikú waa káàkiri


Lasiko ti a ṣakojọpọ iroyin yii tan, inu wahala ati idaamu nla ni ilu mọn-ka olowo kan ti ọpọ awọn eeyan mọ si Obi Cubana wa, lori bi awọn agbebọn ilẹ Biafra ti wọn pe ara wọn ni 'Angry Vipers' ṣe n leri iku si i.
 
Ninu fọnran kan ti awọn agbebọn naa fi sita, eyi ti ẹda rẹ tẹ AWIKONKO lọwọ laipẹ yii ni wọn ti sọ pe Obi Cubana wa lara awọn to n ṣagbatẹru awọn oloṣelu ti ko fẹ ki ilẹ Biafra gba ominira.
 
Wọn tun sọ ninu fọnran naa wi pe awọn fun gbogbo awọn gomina ilẹ Ibo ni ọjọ mọkanlelogun lati mọ bi olori wọn, Nnamdi Kanu yoo ṣe kuro lahamọ DSS to wa lati bi oṣu meloo kan sẹyin.
 
Siwaju sii ni wọn sọ pe Obi Cubana ti ajọ EFCC fẹsun kan wi pe o ledi apo pọ pẹlu awon Fulani to jẹ ọta wọn bii Abba Kyari, gbajugbaja ọlọpaa nni.


No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI