Bi awọn oniṣegun oyinbo, iyẹn dọkita nipinlẹ Kwara ṣe kede sita pe awọn yoo bẹrẹ iyanṣẹlodi ikilọ ọlọjọ meje, pẹlu erongba lati jẹ ki ijọba ṣe ohun tawọn n fẹ fun wọn, ijọba ipinlẹ Kwara labẹ Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti rawọ ẹbẹ wi pe atunṣe yoo wa lori ohun ti wọn fẹ.
Ninu atẹjade ti akọwe agba lẹka eto ilera, Dọkita Abubakar O. Ayinla gbe sita lọjọ Aje, Mọnde, ana lo ti n bẹbẹ pe ki awọn dọkita naa tun ero wọn pa lori iyanṣẹlodi ti wọn fẹẹ bẹrẹ lojiji, ki wọn si wo gbogbo awọn iṣẹ idagbasoke ti ijọba ti ṣe, paapaa lẹka eto ilera.
O ni ọrọ araalu, paapaa awọn oṣiṣẹ ijọba lo jẹ ijọba Kwara logun julọ, eyi ti wọn fi n ṣe gbogbo ohun to yẹ lati rii daju pe wọn jẹ mudunmudun eto ijọba awaarawa.
Ninu atẹjade naa lo ti sọ pe pẹlu bi ijọba ṣe dawọ le iṣẹ to pọ to, sibẹ, wọn tun ṣi ṣe ida aadọrin ohun ti wọn n fẹ fawọn osiṣẹ eto ilera, eyi ti ko yọ gbogbo awọn nnkan to le mu idagbasoke ba ẹka eto ilera kuro.
Siwaju sii lo sọ pe, bo tilẹ jẹ pe awọn ko le da ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ lọwọ kọ lati beere fun ẹtọ wọn labẹ ofin, sibẹ, o ni ki wọn ṣagbeyẹwo gbogbo iṣẹ idagbasoke ti ijọba ti ṣe lẹka eto ilera.
No comments:
Post a Comment