Iyalẹnu lọrọ baale ile, ẹni ọdun mẹtalelogoji kan ti wọn pe orukọ rẹ ni Sanjọ ṣi n jẹ fun ọpọ awọn ara agbegbe Alekuwodo nilu Oṣogbo, ipinlẹ Ọṣun nigba ti wọn lo lu ọmọ rẹ, ọmọ oṣu meji pa nitori ẹkun to n sun.
Ojọ Aiku, Sannde, ana la gbọ pe ọwọ ileeṣẹ ijọba to n ri sọrọ awọn obinrin ati ọmọde, Ministry of Women, Children and Social Affairs tipinlẹ naa lo tẹ Sanjọ, ati iyawo rẹ, ti awọn mejeeji si jẹwọ pe lotitọ ni.
A gbọ pe iya ọmọ naa lo fi silẹ fun Sanjọ lati maa wo o, iyẹn nigba to sare jade lọ. Obinrin naa ko tii rin jinna ti wọn sọ pe ọmọ yii ti bẹrẹ sii sunkun.
Wọn ni gbogbo bi Sanjọ ṣe n bẹ ọmọ naa lati yee sunkun ni ko gbọ ọ, eyi ti wọn lo jẹ ki ọkunrin naa binu, to si luu pa ki iya rẹ too de.
Nigba ti obinrin naa de, to rii pe ọmọ naa ti ku, lawọn mejeeji ba pinnu lati lọ sinku rẹ sinu igbo, nibi ti aṣiri ko ti nii tu sita, ṣugbọn ti wọn lawọn eeyan ri wọn.
Lara awọn to ri wọn lakooko ti wọn n sinku ọmọ naa lo sare lọ pe awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ ijọba yii, ti wọn si sare lọ sibẹ lati lọ mọ ohun to n ṣẹlẹ.
Nigba ti Sanjọ n jẹwọ ẹṣẹ rẹ, o ni lotitọ ni, ati pe iṣẹ eṣu ni. O jẹ ko di mimọ pe kii ṣe akọkọ ree ti ọmọ yoo maa ku mọ awọn lọwọ.
Kọmiṣanna fun ileeṣẹ ijọba naa, Olubukọla Ọlabọọpo, ninu ọrọ rẹ ṣalaye pe ọdun 2008 ni Sanjọ ati iyawo rẹ fẹ ara wọn, ti wọn si bimọ marun-un. Meji ninu awọn ọmọ naa ni wọn lu pa funra wọn, ti wọn si gbe ọkan ninu wọn lọ sọnu.
O ni iyawo Sanjọ lo jẹwọ pe nitori iṣẹ ati oṣi to n ba wọn finra lawọn ṣe gbe igbesẹ ọhun, nitori pe awọn ko rowo tọju wọn.
Ọlabọọpo wa sọ pe awọn ti fa tọkọ tiyawo naa le awọn ọlọpaa lọwọ, ati pe awọn ko ni gba iru iwa buruku bayii laaye nipinlẹ naa.
No comments:
Post a Comment