Gbogbo awọn agbaagba ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC kaakiri ipinlẹ Kwara l'ọjọ Aje, Mọnde, ijẹta, tun ti fabuku kan Minisita fun eto ibanisọrọ ati aṣa lorilẹ-ede Naijiria, Alaaji Lai Muhammed, nibi ti wọn tun ti fẹsun kan an pe o n fẹnu wa rọọfu si Gomina Abdulrahman Abdulrazaq.
Opin ọsẹ to kọja yii ni agbarijọ awọn agba ẹgbẹ ati adari ẹgbẹ oṣelu APC, ẹka tipinlẹ Kwara, bu ẹnu atẹ lu bi minisita naa ṣe n bu Abdulrahman Abdulrasaq, to si sọrọ nipa bi wọn ṣe ṣe owo ti wọn pa wọle lasiko eto idibo to waye lọdun 2019.
Agbẹnusọ fun awọn agba ẹgbẹ ọhun nipinlẹ Kwara, Ambassador Nurudeen Mohammed, lo sọrọ naa fawọn oniroyin niluu Ilọrin. O sọ pe ko si ẹni to mọ Lai ninu eto oṣelu ipinlẹ Kwara titi di ọdun 2002, ẹni ti ko ba si ṣe nidii pẹpẹ, ko yẹ ko jẹ nidii pẹpẹ, tori pe ilu Eko lo fi ṣe ibugbe, ti yoo si maa sare wale bi eto idibo ba ti sun mọ etile, lati gba agbara lọwọ awọn ọmọ ilu ti wọn n gbe ilu, o ni ala ti ko le ṣẹ ni.
Wọn juwe Lai gẹgẹ bii ọmọ Eko to fẹẹ maa dipo oṣelu mu nipinlẹ Kwara, tori pe o ti jẹ olori oṣiṣẹ nipinlẹ Eko ri, bakan naa lo ti jẹ kọmiṣanna tẹlẹ nipinlẹ Eko.
Fun idi eyi, ki Lai yee yẹnu gẹrẹ si gomina mọ, tori pe ki i ṣojulowo ọmọ Kwara, ọmọ ipinlẹ Eko ni.
No comments:
Post a Comment