MTN tọwọ́ bọ̀wé àdéhùn pẹ̀lú ìjọba Kwara lórí ètò ìlera fáwọn aráàlú - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, November 24, 2021

MTN tọwọ́ bọ̀wé àdéhùn pẹ̀lú ìjọba Kwara lórí ètò ìlera fáwọn aráàlú


Lọjọ Iṣẹgun, Tuside ana nijọba ipinlẹ Kwara labẹ Gomina AbdulRahman AbdulRazaq tọwọ bọ iwe adehun pẹlu ileeṣẹ ikansira-ẹni nni, MTN lojuna lati jẹ kawọn araalu jẹ anfaani eto ilera to peye.
 
Ọdun kan gbako ni iwe adehun ati asọyepọ ti wọn tọwọ bọ naa yoo ṣiṣẹ mọ, lẹyin eyi ni wọn yoo tun ṣẹṣẹ pinnu lati jokoo papọ lati mọ boya wọn yoo tun sun un siwaju tabi daa duro.
 
Iwe adehun yii, gẹgẹ bi a ṣe gbọ, wọn ni yoo mu kawọn eleto ilera maa gbe ayẹwo ilera lọ ba awọn araalu nile wọn, lai jade lọ sile iwosan.
 
Nibi iṣide eto naa ti wọn pe ni MTN Y’ello Doctor Primary Health Care Intervention, to waye niluu Ilọrin  ni igbakeji gomina, Kayọde Alabi ti sọ pe lara awọn ileri wọn fun araalu ni pe wọn yoo jẹ mudunmudun eto oṣelu awaarawa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI