Gbajugbaja Ajihinrere-binrin kan lo ti sọ laipẹ yii wi pe oun ri oludasilẹ ṣọọṣi Synagogue Church of All Nations (SCOAN), Oloogbe TB Joshua, ati oludasilẹ Church of God Mission International, Biṣọọbu Benson Idahosa lọrun apaadi.
Ajihinrere ọhun lo sọ eyi ninu fọnran kan to gbe sita, eyi to n kaakiri ori ikanni ayelujara lọwọlọwọ, to si ni ṣe lawọn mejeeji n sunkun kikoro lọrun apaadi ti wọn wa.
Obinrin naa tun tẹsiwaju pe ṣe loun ri Biṣọọbu Idahosa pẹlu ṣẹkẹṣẹkẹ lọrun, to n sunkun nitori bo ṣe gba awọn ọmọ ijọ laaye lati maa lo awọn ẹgba ọrun ati ọwọ, iyẹn Jewelries.
Fọnran naa ree:
No comments:
Post a Comment