Ìlú Abẹ́òkúta fẹ́ẹ́ gbàlejò àwọn èèyàn pàtàkì-pátákí, gbajúgbajà sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ fẹ́ẹ́ ṣayẹyẹ ọdún mẹwàá lórí afẹ́fẹ́ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, November 10, 2021

Ìlú Abẹ́òkúta fẹ́ẹ́ gbàlejò àwọn èèyàn pàtàkì-pátákí, gbajúgbajà sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ fẹ́ẹ́ ṣayẹyẹ ọdún mẹwàá lórí afẹ́fẹ́


Gbogbo eto lo ti fẹẹ pari bayii, pẹlu bi gbajugbaja sọrọsọrọ nni, Kọmureedi Samuel Olufẹmi Omilani ṣe fẹẹ ṣayẹyẹ ọdun kẹwaa to ti n sọrọ lori afẹfẹ, iyẹn reduo ati tẹlifiṣan.

Ọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kọkanlelogun, oṣu yii ni ayẹyẹ onibẹta ọhun fẹẹ waye niluu Abẹokuta. Gbọngan ayẹyẹ ti Imperial, to wa ni Quarry Road, Abẹokuta, ipinlẹ Ogun ni yoo ti waye, bẹrẹ lati aago mejila ọsan.

Lara awọn alakalẹ fun ayẹyẹ naa ni wọn ti gbe eto pataki kalẹ fawọn ibeji to jọ ara wọn, nibi ti awọn ibeji to jọ ara wọn yoo ti figagbaga. Eyi to ba si jawe olubori ninu wọn yoo gba ẹbun rabandẹ-rabandẹ lọ sile.
 
Bakan naa ni Omilani tun fẹẹ ṣe ikojade iwe to n sọ nipa igbesi aye awọn ẹranko ati ẹyẹ loriṣiriṣi, iwe naa lo pe akọle rẹ ni 'AYE AWỌN ẸRANKO'.
 

Eyi ti wọn fẹẹ fi kadi rẹ nilẹ ni imọriri awọn to ti ko ipa ribiribi to jọju lawujọ, ti wọn yoo si gba aami ẹyẹ idalọla ọlakan-o-jọkan.
 
Olufẹmi Omilani, kii ṣaimọ foloko lagboole sọrọsọrọ, paapaa nipinlẹ Ogun, koda, oun ni alaga ẹgbẹ naa naa, FIBAN nipinlẹ ọhun, to si ti mu idagbasoke ti wọpọ ba ẹgbẹ naa lati bi ọdun mẹrin le, to ti wọn ti dibo yan an.
 
AWIKONKO gbọ pe ilu-mọ-n-ka sọrọsọrọ agbaye nni, Ọgbẹni Kọlawọle Adejojo ti ọpọ wọn ololufẹ rẹ mọ si Kasnaty Sugar olugbalejo ọjọ naa, nigba ti Aarẹ ẹgbẹ awọn sọrọsọrọ lorilẹ-ede Naijiria, Kọmureedi Desmond Abiọdun Nwachukwu ni olugbalejọ agba ọjọ naa.
 
Gbajugbaja olorin Isilaamu nni, Alaaji Bukọla Alayande, ẹni tawọn eeyan tun mọ si Ere Asalatu, pẹlu awọn olori miran ni yoo dalu bọlẹ gidi fawọn alejo ọjọ naa, nigba ti Bẹbẹ Musiliu, Tolu Ọnafọwọkan ati MC Governor yoo dari ayẹyẹ.
 
Ko tan sibẹ, iroyin to tẹ wa lọwọ sọ pe Aṣọ Ẹbi, iyẹn Ankara ti wọn ta ni ẹgbẹrun mẹrin aabọ, iyẹn ọpa mẹfa, ati ẹgbẹrun mẹta fun ọpa mẹrin lawọn eeyan yoo fi wọle sinu gbọngan ayẹyẹ ọjọ naa. Ko wọṣọ, ko wọle ni.
 
Oloye Olumide Aderinokun ni alaga ọjọ naa, nigba ti Ọnọrebu Ibrahim Isiaka yoo jẹ olufilọlẹ agba eto onibẹta yii.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI