Ijọba ipinlẹ Kwara labẹ Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti fidi rẹ mulẹ wi pe awọn ti ṣetan lati kọ ọja igbalode pẹlu awọn ṣọọbu loriṣiriṣi fun irọrun ati igbadun araalu, paapaa awọn ọlọja.
Yatọ si eyi, ijọba Kwara tun lawọn ti ṣetan lati kọ ileeṣẹ panapana, ibudo ile itaja nla, iyẹn Warehouse, Odo Ẹran fawọn alapata, Ileeṣẹ Okoowo atawọn mi-in to le mu irọrun de ba eto ọrọ aje.
Ilu Gbugbu to wa nijọba ibilẹ Edu nijọba Kwara lawọn fẹẹ kọ gbogbo awọn nnkan wọnyi si, eyi to ni yoo mu idagbasoke ba eto ọrọ aje agbegbe naa, ti yoo si jẹ ki owo to n wọle sipinlẹ naa lọ soke sii.
Ẹkunrẹrẹ rẹ ree: IROYIN NAA
No comments:
Post a Comment