Haaaa! Àwọn agbébọn kọlu ilé Ọ̀jọ̀gbọ́n Bánjí Akíntóyè, wọ́n fẹ́ẹ́ pa á dànù ni - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, November 3, 2021

Haaaa! Àwọn agbébọn kọlu ilé Ọ̀jọ̀gbọ́n Bánjí Akíntóyè, wọ́n fẹ́ẹ́ pa á dànù ni


Iroyin to tẹ wa lọwọ ti fi ye wa pe awọn agbebọn kan tẹnikẹni ko tii mọ ti yawọ ile agba ilẹ Yoruba nni, Ọjọgbọn Banji Akintoye, iyẹn olori ẹgbẹ Ilana Ọmọ Oodua to wa nilu Ado-Ekiti, ipinlẹ Ekiti.
 
Ọjọ Abamẹta, Satide, ọsẹ to kọja yii la gbọ pe awọn agbebọn naa yawọ ile Ọjọgbọn Akintoye.

AWIKONKO gbọ pe ori aga to wa lẹnu ọna abawọle sinu ọgba ile naa la gbọ pe awọn agbebọn naa gun, ti wọn fi dabọn bolẹ, sinu ọgba ile ọhun.

Lara awọn to fi iṣẹlẹ naa to wa leti sọ pe baba naa ni wọn wa wa, ṣugbọn ti ko si nile lakooko naa. Lẹyin ikọlu ọhun, wọn ni ọta ibọn ti wọn ri ṣa ninu ọgba naa jọ ti ibọn Ak-47.
 
Bẹẹ la gbọ pe iwadii awọn ọlọpaa ti bẹrẹ lati mọ otitọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI