Gómìnà tẹ́lẹ̀rì n'ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Ràṣídì Ládọjà pàdánù àbúrò rẹ̀ n'Íbàdàn - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, November 26, 2021

Gómìnà tẹ́lẹ̀rì n'ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Ràṣídì Ládọjà pàdánù àbúrò rẹ̀ n'Íbàdàn


Gomina tẹlẹri nipinlẹ Ọyọ, Sẹnetọ Rashidi Adewọlu Ladọja, ti padanu ọkan pataki lara awọn aburo rẹ, Alaaji Lateef Ladọja nilu Ibadan, ipinlẹ naa.
 
Alẹ Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii, la gbọ pe Alaaji Ladọja, ẹni tọpọ eeyan tun mọ si Baba Kekere jade laye lẹyin aisan rampẹ kan ti wọn loo da a dubulẹ.
 
Latigba ti iroyin iku naa ti jade sita lawọn ọtọkulu ati alẹnulọrọ lawujọ, paapaa nidii oṣelu ti n ranṣẹ ibanikẹdun si ẹgbọn oloogbe, Sẹnetọ Ladọja, ẹni to tun jẹ Osi Olubadan tilẹ Ibadan.
 
Amofin-Agba Niyi Akintọla, ṣapejuwe oloogbe naa gẹgẹ bii oniwa tutu bii adaba nigba aye ẹ.
 
Gẹgẹ bo ṣe sọ, “Nigbati ta a gbọ pe iku ti ja oniwa tutu bii adaba yii gba mọ wa lọwọ, ibeere to koko wa sẹnu gbogbo wa ni pe, ki lode to jẹ Ladọja niku mu lọ, ki lo ṣẹlẹ gan-an?
 
“Sugbon ta ni wa lati ba Ọlọrun Ọba wijọ nipa igba ti yoo mu ẹda ọwọ ẹ lọ nigba to ba wu u.”
 
Agba Amofin naa waa gbadura pe ki Ọlọrun fi alijanna onidẹra jinki oloogbe naa, ko si fun gbogbo ẹbi ẹ lẹmi-in itẹmọra lati le gba iku baba kekere bi amuwa Ọlọrun.
 
Ninu ọrọ ibanikẹdun tiẹ, Oludije fun ipo gomina ipinlẹ Ọyọ, Mọgaji Joseph Tegbe, gba pe aiduro deede eto aabo orileede yii lo ṣokunfa iku aburo Ladọja.
 
Ọ ni, “Mo ba Agba-Oye Rashidi Adewọlu Ladọja kẹdun iku aburo wọn to tun jẹ ọkan ninu awọn alatilẹyin wọn. Ki Ọlọrun ba ni tu idile wọn ninu.
 
“Iṣẹlẹ iku Baba kekere lo tun mu wa ranti idi to ṣe ṣe pataki ki awọn ijọba wa wa nnkan ṣe sọrọ eto aabo kiakia, nitori a o le ṣe bayii maa padanu awọn eeyan pataki sọwọ iku ti ki i ṣe afọwọ-rọri-ku”.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI