Gbajúmọ̀ sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ fẹ́ẹ́ fi ẹ̀bun ọdún tọrẹ fáwọn arúgbó káàkiri ìpínlẹ̀ Ògùn lọ́jọ́ kejìlá oṣù kejìlá - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, November 29, 2021

Gbajúmọ̀ sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ fẹ́ẹ́ fi ẹ̀bun ọdún tọrẹ fáwọn arúgbó káàkiri ìpínlẹ̀ Ògùn lọ́jọ́ kejìlá oṣù kejìlá


Gbogbo eto lo ti fẹẹ pari bayii fun ọkan lara awọn gbajugbaja sọrọsọrọ ori redio ati telifiṣan nni, Kọlawọle Atanda Adejojo, ẹni ti ọpọ awọn eeyan mọ si Kasnaty Shugar lati fi ẹbun ọdun tọrẹ fawọn araalu.

AWIKONKO gbọ pe kii ṣe akọkọ ree ti Kasnaty yoo maa fi iru ẹbun ọdun bayii tọrẹ fawọn arugbo, ṣugbọn eyi to fẹẹ waye lọjọ kejila, oṣu kejila, ọdun 2021 yii fẹẹ gbọna ara ọtọ yọ.
 
Iroyin to tẹ wa lọwọ sọ pe awọn arugbo ti ko din ni aadoje, iyẹn 150 ni ọkunrin to fẹran lati maa jẹ ẹja tutu naa fẹẹ foju aanu wo kaakiri ipinlẹ Ogun lọjọ naa, ti a si tun gbọ pe awọn kan ti dide lati tun darapọ mọ eto ọhun lati le jẹ ki awọn arugbo naa jẹ igba, iyẹn 200.

Awọn arugbo ti ọjọ ori wọn bẹrẹ lati ọgọta ọdun, lọ soke, 60+, ni ọkunrin to filu Abẹokuta ṣe ibugbe naa fẹẹ fi ẹbun ọdun ta lọrẹ. Kii ṣe pe o fẹẹ fi ẹbun ọdun ta wọn lọrẹ nikan, o fẹẹ ṣe ọdun fun wọn gidi lara ọtọ ni.

Iyẹn nikan tun kọ o, wọn ni aṣọ ẹgbẹjọda ti Kasnaty ra ni gbogbo awọn arugbo naa yoo wọ lọjọ naa, lati le da awọn to fẹẹ jẹ anfaani ẹbun ọdun yii mọ, ọfẹ si ni wọn lo fun wọn laṣọ, ko da, ti wọn ni o tun fun wọn lowo ti wọn yoo fi ran aṣọ ọhun funra wọn.
 
Otẹẹli Daktad to wa ladugbo Quarry nilu Abẹokuta, ipinlẹ Ogun ni eto naa yoo ti waye, bẹrẹ lati agogo mẹrin irọlẹ
 


No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI