Bi ere, bi awada, bi ala lọrọ iku alaga fẹgbẹ awọn akọroyin nipinlẹ Ogun, Kọmureedi Olusọji Samson Amosu ṣi n jẹ titi di asiko ti a pari akojọpọ iroyin yii tan.
Aarọ oni, ọjọ Aiku, Sannde la gbọ pe Kọmureedi Amosu jade laye, lẹyin aisan rampẹ.
Nigba to n fidi iroyin ọhun mulẹ, akọwe ẹgbẹ naa, Kọmureedi Ayọkunle Ewuoṣo jẹ ko di mimọ pe ibanujẹ nla niku Amosu jẹ, paapaa lagboole akọroyin.
Ninu atẹjade to fi kede iroyin iku naa, Ewuoṣo kede wi pe ẹgbẹ naa yoo wa ni ikẹdun fun ọjọ meje gbako, bẹrẹ lati ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹẹdogun, oṣu yii.
Bẹẹ lo fi kun ọrọ re wi pe awọn yoo kede bi eto isinku ọkunrin naa yoo ṣe lọ laipẹ ọjọ.
No comments:
Post a Comment