Ẹgbẹ́ PCRC fi oyè bàbá ìsàlẹ̀ dá Olóyè Adérìnókùn lọ́lá nìpínlẹ̀ Ògùn - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, November 12, 2021

Ẹgbẹ́ PCRC fi oyè bàbá ìsàlẹ̀ dá Olóyè Adérìnókùn lọ́lá nìpínlẹ̀ Ògùn


Ẹgbẹ to n ṣa arena laaarin ọlọpaa ati araalu, iyẹn Police Community Relations Committee (PCRC), ẹka tipinlẹ Ogun l'Ọjọbọ , Tọside ana ti fi oye baba isalẹ ti ko wọpọ da ọkan pataki lara awọn oloye ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP, Oloye Olumide Aderinokun lọla.

AWIKONKO gbọ pe, ko si ohun meji to mu ki ẹgbẹ PCRC fi oye naa da oludasilẹ ajọ alaanu Olumide and Stephanie Aderinokun Foundation yii lọla, bi ko ṣe ti awọn ipa ribiribi to ti ko lawujọ, nipa idagbasoke ati ilọsiwaju.
 
Odu ni Oloye Aderinokun, kii ṣaimọ foloko kaakiri ipinlẹ Ogun ati orilẹ-ede Naijiria lapapọ.
 
Ilegbe ọga ọlọpaa to wa nipinlẹ Ogun, iyẹn Nigeria Police Officers’ Mess to wa ni Ibara Housing Estate, niluu Abẹokuta ni eto naa ti waye, nibi ti awọn eeyan jankanjakan, atawọn oloṣelu laaarin gbungbun ipinlẹ Ogun ti peju-pesẹ.
 
A gbọ pe awọn oloye ẹgbẹ PCRC naa ni wọn ri ipa ti Oloye Aderinokun, ẹni to tun jẹ Akinruyiwa tilu Owu n ko lawujọ, ti wọn si lawọn pinnu lati fi jẹ baba isalẹ, iyẹn Golden Patron wọn fun gbogbo ipinlẹ Ogun.

Laaarin oṣu mẹta si asiko ti a wa yii, awọn ipa manigbagbe ni Oloye Aderinokun ti fi lọlẹ kaakiri ipinlẹ Ogun, lara rẹ ni ipese omi fawọn araalu, riro awọn ọlọja lagbara pẹlu owo, fifun awọn akẹkọọ lẹbun ẹkọ ọfẹ ati bẹẹbẹẹlọ.

Lara awọn to wa nibi akanṣe eto naa ni Olori Olowu tilu Owu, Olori Ọlatunbọsun Dosunmu; iyawo Aarẹ orilẹ-ede yii tẹlẹri, Oloye (Arabinrin) Bọla Ọbasanjọ; Kọmiṣanna tẹlẹri fọrọ idagbasoke agbegbe, Ọmọọba Lekan Tejuoṣo; aṣoju ọga ọlọpaa nipinlẹ Ogun, ACP Musiliu Aliu; Alaga ẹgbẹ oṣelu PDP nipinlẹ Ogun, Ọnọrebu Sikirulai Ogundele atawọn mi-in.

Nigba to n fi imọriri rẹ han, Oloye Aderinokun dupẹ gidigidi lọwọ ẹgbẹ PCRC, to si tun ṣe ileri wi pe oun ko ni dawọ iranlọwọ ati igbelarugẹ gbogbo iṣẹ wọn duro.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI