Oluwo tilu Iwo, nipinlẹ Ọṣun, Ọba Abdulrọsheed Adewale Akanbi, pe gbobo awọn ọba ilẹ Yoruba, awọn agbaagba, atawọn alẹnulọrọ lati dide lọ ba Aarẹ Muhammadu Buhari lori bi wọn ṣe maa gba olori ajijangbara ilẹ Yoruba, Oloye Sunday Adeniyi Adeyẹmọ, ti ọpọ awọn eeyan tun mọ si Sunday Igboho silẹ.
Kabiyesi naa sọ pe gbigba Igboho silẹ kuro lahamọ to wa yoo tubọ mu idagbasoke ati ilọsiwaju ba iṣọkan orilẹ-ede Naijiria, to si n rawọ ẹbẹ si gbogbo awọn ọba alaye lapapọ lati fọwọsowọpọ nipa dide iranlọwọ fun ọmọ wọn, Sunday Igboho.
Ninu ọrọ rẹ, Kabiyesi sọ pe, “Awuyewuye to n lọ lori bi Sunday Igboho ṣe wa lọgba ẹwọn yẹn le wa sopin ti awọn ori-ade ati awọn lookọlookọ nilẹ Yoruba ba dide tọ Aarẹ Buhari lọ.
“Ọmọ wa ni Sunday Igboho, o ti ṣe awọn aṣiṣe kan nipa fifi agbara wa ominira ilẹ Yoruba. Ọwọ to fi mu ọrọ yẹn lo dabaru gbogbo nnkan.
“Amọ ṣa, ki gbogbo wa ṣiṣẹ papọ lati gba Igboho silẹ nipa titọ Aarẹ lọ, ka si jọ sọrọ lori ẹ. Tijọba apapọ naa ba ṣe eleyii fun wa, yoo jẹ ki iṣọkan tubọ nipọn si i lorileede yii.
“Ijọba apapọ nikan lo le ba wa gba itusilẹ Igboho, a oo si gboriyin fun wọn ti wọn ba gbe igbesẹ agba ati ti iṣọkan yii.”
Ọba Akanbi tun ke si gbogbo awọn ọmọ orilẹ-ede yii lati tubọ maa wa iṣọkan ati idagbasoke ilẹ wa.
No comments:
Post a Comment