Baba agbalagba, ẹni ọdun mọkanlelaadọrin kan, Karimu Modupẹ ti foju ba ile-ẹjọ Majisireeti to wa nilu Oṣogbo, ipinẹ Ọṣun lori ẹsun wi pe o n da alaafia ilu laamu.
A gbọ pe Karimu atawọn kan tawọn ti na papa bora ni wọn ko awọn nnkan ija oloro lọ sori ilẹ ẹnikan ti ọn pe ni Kunle Johnson, ti wọn si ṣee leṣe lọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu kẹwaa, ọdun yii lagbegbe Woru nilu Oṣogbo.
A gbọ pe bi wọn ṣe lu Johnson lalubolẹ tan, ni gbogbo wọn salọ, ṣugbọn ti ọwọ ọlọpaa pada tẹ Karimu.
Nigba to paṣẹ, Onidajọ Aṣimiu Adebayọ sọ pe ki wọn lọ fi Karimu pamọ sọgba ẹwọn titi igbẹjọ miran yoo fi waye, tabi ko lọ san owo itanran miliọnu kan naira pẹlu oniduro kan ṣoṣo to n gbe layika kootu, gẹgẹ bi beeli rẹ.
Bẹẹ lo sun igbẹjọ siwaju di ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu kejila, ọdun yii.
No comments:
Post a Comment