Iroyin to tẹ AWIKONKO lọwọ ti sọ pe awọn agbebọn kan ti ji gbajumọ Imaamu agba nilu Abuja ati ọmọ rẹ gbe salọ, ti ko si tii sẹni to le sọ pato ibi ti wọn gbe wọn lọ, titi di asiko ti a pari akojọpọ iroyin yii.
Abdullahi Abubakar Gbedako, loukọ Imaamu agba naa ni mọṣalaṣi Yangoji to wa l'Abuja.
Lara ohun ti a gbọ ni pe ṣe ni awọn agbebọn naa yawọ ile Imaamu yii, ti wọn si ji oun ati awọn ọmọ rẹ meji, Aliyu Usman Abubakar, ọmọ ọdun mejilelogun ati Ibrahim Abubakar, toun jẹ ọmọ ọdun mọkanla gbe salọ.
Nnkan bi aago mọkanla aabọ alẹ, ọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ to kọja yii la gbọ pe awọn ajinigbe naa gbe mọto nla meji wọ adugbo ọhun, ti wọn si fo fẹnsi wọle sinu ọgba ile naa.
Ṣe ni iro ibọn n pe ara wọn ran niṣẹ lakooko ikọlu naa.
Ni bayii, AWIKONKO gbọ pe miliọnu mẹwaa naira lawọn ajinigbe naa n beere lati fi tu awọn eeyan naa silẹ, bẹẹ si ni agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa Abuja, Josephine Adeh, fidi rẹ mulẹ.
O lawọn ti bẹrẹ iwadii wọn lati rii pe wọn rọwọ to awọn ọdaran naa, ti wọn si gba awọn ti wọn jigbe gba kuro lọwọ wọn lai farapa.
No comments:
Post a Comment