Gomina AbdulRahman AbdulRazaq tipinlẹ Kwara ti sọ ọ sita gbangba wi pe ko dara lati maa pa awọn ile ẹkọ tabi ile iwosan to ti dẹnukọlẹ ti, ki wọn too kọ tuntun, nitori pe ko dara fun ijọba gidi to mọ ohun to n ṣe.
AbdulRazaq sọ pe ohun to bojumu ni lati maa ṣe ohun tawọn araalu n fẹ nipa ṣiṣe atunṣe awọn ibi to ti dẹnukọlẹ patapata, nigba ti wọn ba tun n kọ tuntun, fun igbayegbadun araalu.
Ọjọ Aje, Mọnde to kọja yii ni Gomina AbdulRazaq sọrọ naa jade, to si sọ pe lara awọn ipinnu oun ni lati maa ronu kan oun to ba ṣe pataki si awọn araalu, ati awọn nnkan to le jẹ ki araalu jẹ mudunmudun eto oṣelu awaarawa.
Siwaju sii lo tẹnu mọ ọn wi pe ohun to ba yẹ lo yẹ ki ijọba gbajumọ bii eto ẹkọ to peye, eto ilera to jọju, ati awọn ẹtọ ti ko ni ẹlẹyamẹya ninu.
Ninu ọrọ rẹ, o sọ pe awọn alatako awọn ti n pariwo tipẹ wi pe awọn ko ri iṣẹ tawọn n ṣe, ti wọn ko si ri ipa rere ti wọn fẹẹ fi lelẹ. O ni ijọba kii ṣe nipa awọn ipa ti wọn fẹẹ fi lelẹ, bi ko ṣe lati ṣatunṣe awọn ohun to ti wa nilẹ tẹlẹ, ko si wa bo ṣe yẹ ko wa.
"Ọna kan ṣoṣo ti a le fi ṣe ojuṣe wa ni lati tun ileewe ati ọsibitu ṣe, ko si wa nipo to yẹ. Awọn eeyan mọ pe ipo ti a ba ilu yii ko ba oju mu to rara, eyi ti awọn olori wọn ti ba awọn banki jẹ gidi, ti ko si jẹ ki ilu lọ siwaju."
O wa jẹ ko di mimọ pe gbogbo ohun to ba nilo atunṣe lawọn yoo ṣe, dipo ki wọn kan maa dawọ le iṣẹ ti ko nitunmọ, nitori pe irọrun araalu lo jẹ wọn logun julo.
No comments:
Post a Comment